Subscribe to the mailing list:
Our Choice for you
Eleyi ni afikun alaye lori awọn ojuse obinrin musulumi, ti alaye nipa awọn ẹtọ obinrin musulumi si jẹ ohun ti wọn fi tẹle.
Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sise alaye ipo ti awujọ gbe obinrin si pẹlu afiwe rẹ si ipo ti Islam gbe obinrin si. (ii) Sise ni alaye abala diẹ ninu awọn ojuse obinrin musulumi si gbogbo awọn agbegbe ti o nii se pẹlu igbesi aye won.
Eyi ni abala idahun si awọn ibeere ti o jẹyọ lati ibi idanilẹkọ yii.
Abala yii sọ nipa awọn ọna mẹrin ti ede-aiyede ma ngba wa laarin lọkọ-laya, oludanilẹkọ si tun se alaye awọn igbesẹ ti Islam fẹ ki a gbe nigbati ede-aiyede ba waye laarin lọkọ-laya.
Alaye ni abala akọkọ Idanilẹkọ yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Sisọ nipa pataki ati anfaani ti o wa nibi igbeyawo, (ii) Sise alaye awọn ojuse lati ọdọ ọkọ si iyawo rẹ, bẹẹ naa ni awọn ojuse lati ọdọ iyawo si ọkọ rẹ, (iii) Sise apejuwe oniranran ede-aiyede laarin lọkọ-laya.
Abala yii ni o gbẹyin idanilẹkọ yii ti o si kun kẹkẹ fun awọn ibeere pẹlu awọn idahun wọn.
Oro waye ni apa yii lori awọn orisirisi ẹkọ ti o yẹ ki a ni akolekan rẹ lori imọ tabi ẹkọ ti a nwa, ti abala akọkọ ninu ibeere ati idahun si gbẹyin rẹ .
Koko idanileko yii: (1) Awọn ẹsẹ Alukuraani ti nsọ nipa pataki Imọ ati awọn Onimimọ. (2) Alaye iru awọn imọ ti o le se wa ni anfaani ati eyi ti ko le mu anfaani kankan wa fun wa. (3) pataki wiwa imọ ẹsin pẹlu awọn nkan ti a gbọdọ sọ ni oju ọna imọ wiwa.
Wiwa ojurere Olohun, kiko awon ese sile, siso enu aala Olohun, didunni mo iranti Olohun ati beebee lo ni awon eko ti akosile yi so nipa won. Eleyi si ni die ninu awon ojuse Musulumi ti o ba gbero lati se irinajo fun ise Haj tabi Umrah.
Olohun se ipari aawe ati ojo kewa osu Dhul-hijja ni odun fun awa Musulumi. Ibani soro yi n so nipa awon eko ti Islam ko wa nipa odun aawe. Ninu re ni ki Musulumi wo aso ti o dara ti o si wuyi ni ojo odun lati gbe ojo yi laruge. Ojise Olohun si pase wipe ki gbogbo Musulumi jade lo si aaye ikirun fun odun yii.
Recently Added ( Yoruba )
Audios
( Yoruba )
2014-12-16
Ibanisọrọ yi da lori alaye nipa aleebu ti o wa nibi iwa igberaga ati awọn oore ti o nbẹ nibi itẹriba.
Audios
( Yoruba )
2014-12-16
Awọn koko Idanilẹkọ yi: (i) Awọn ohun mẹta ti o maa nse okunfa iforikanlẹ itanran igbagbe lori Irun. (ii) Awọn aaye ti a ti maa nse iforikanlẹ itanran igbagbe, siwaju salamọ ni tabi lẹyin salamọ. (iii) Awọn idajọ ti o rọ mọ iforikanlẹ itanran igbagbe.
Audios
( Yoruba )
2014-12-16
Idanilẹkọ yi da lori wipe idakeji ẹbọ sise ni sise Ọlọhun Allah ni aaso tabi gbigba A ni okan soso pẹlu ẹri Alukuraani ati ẹgbawa hadisi. Alaye tẹsiwaju nipa itumọ ẹbọ sise pẹlu awọn ọna ti ẹbọ sise pin si.
Fatawa
( Yoruba )
2014-12-16
Idajo esin lori yiyan nafila ni ojo alaruba ti o kehin ninu osu Safar ati idajo esin lori wipe irufe nafila bee adadasile ninu esin ni.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
Idanilẹkọ yii da lori awọn koko mẹta wọnyii: (i) Pataki asepọ jijẹ ọmọ iya ninu ẹsin. (ii) Ẹsan ti o wa fun asepọ ọmọ iya ninu ẹsin. (iii) Awọn nkan ti o maa nba jijẹ ọmọ iya ninu ẹsin jẹ.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
Awọn koko idanilẹkọ yii: (1) Alaye itumọ ibẹru Ọlọhun ninu irun kiki pẹlu apejuwe rẹ nibi isesi awọn ẹni-isaaju ti wọn jẹ ẹni-rere. (2) Itaniji si awọn isesi kan ti ko lẹtọ ninu irun. (3) Awọn ohun ti o le se okunfa ibẹru Ọlọhun ninu irun.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
Idanilẹkọ yi sọ nipa ohun ti a npe ni Alukuraani pẹlu awọn ẹri lati inu ayọka rẹ, ọrọ si tun waye lori awọn ọla ti o wa fun kika rẹ ati awọn ẹkọ ti o rọ mọ kike rẹ.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
Ibanisọrọ yii sọ daradara ti o yẹ ki o maa ti ọwọ musulumi kan jade si ọdọ musulumi keji ati awọn aburu ti o yẹ ki wọn maa le jina si ara wọn.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
1- Idanilẹkọ yi sọ nipa itumọ aladugbo pẹlu itọka rẹ lati inu Alukurani, bakannaa ọrọ tun waye lori diẹ ninu awọn iwọ aladugbo gẹgẹ bii ki Musulumi jẹ ki ọkan aladugbo rẹ balẹ, ki o ma je ki suta tabi aburu wa lati ọwọ rẹ si aladugbo rẹ. 2- Itẹsiwaju alaye lori awọn iwọ aladugbo, ọrọ waye nibẹ wipe ninu awọn iwọ aladugbo yoku ni: didaabobo o, sise daradara si i, sise amumọra fun aburu ọwọ rẹ ati bẹẹbẹẹ lọ.
Audios
( Yoruba )
2014-12-10
Koko idanilẹkọ yii da lori awọn nkan mẹta wọnyii: (i) Ọla ti nbẹ fun ibẹru Ọlọhun, (ii) Pataki ibẹru Ọlọhun, (iii) Anfaani ti o wa nibi bibẹru Ọlọhun.
Go to the Top